IKANKUN LORI ILẸKUN RẸ

IKANKUN LORI ILẸKUN RẸ

Iwe Bibeli ninu Ifihan 3:20, Jesu wi pe “kiyesi, emi duro ni enu ilẹkun, mo si n kan ilẹkun, ti ẹnikẹni ba gbọ ohun mi ti o si si ilẹkun, emi yi o wole tọ ọ wa, emi yio si jẹun pẹlu rẹ ati oun pẹlu mi.”

Ibeere ni abala yii ni wipe: Njẹ iwo ti ni erongba lati si ilẹkun ọkan re fun Jesu, Olugbala araye? Kiyesi ‘ẹnikẹni’, eyi tumo si wipe ẹya rẹ, awọ rẹ, ipilẹ tabi orisun rẹ, iṣẹ rẹ, igbagbọ rẹ, ẹsin rẹ, ipo ti o wa tabi ohun atẹyinwa ko ni ipa kankan lati ko ninu oro yii.

Ni asiko ti o ba se afokansi lati gba Jesu laaye ninu ọkan rẹ yi o gba iṣakoso aye rẹ, yi o si tọju rẹ ni ona ti ẹnikẹni l’orilẹ aye ko le e se.

OUN KAN ILEKUN RẸ LỌWỌLỌWỌ! JESU NDURO NI ẸNU ILẸKUN OKAN RẸ! O LẸ SẸ NKANKAN LATI JẸ KI O WỌLE NIPA PIPE JESU NI IDAKẸJẸ LATI WA JẸ OLUWA AYE RẸ. MA ṢE TA A NU!

Ninu iwe Matiu 11:30, Jesu ṣo wipe “Nitori ajaga mi rọrun, ẹru mi si fuyẹ”. Ko beere ohun ti o pọju: Akọkọ, igbagbọ rẹ: ki o gbagbo wipe oun ni Ọmọ Olọrun ati pe o san gbese ẹsẹ rẹ nipa kiku fun ọ ni ori igi agbelebu. Ikeji, gba wipe ẹlẹsẹ ni ọ. Iketa, Ronupiwada, ki o si ke pe e ki o wẹ o pelu eje iyebiye rẹ ti o ta sile fun iwọ ati emi.

Lẹyin eyi, o ti yege lati ba Jesu jẹun. Yi o kọ orukọ rẹ sinu iwe iye, emi rẹ yi o bẹrẹ si ni ṣiṣẹ ninu rẹ lati se ifẹ Ọlọrun. Nipasẹ eyi, satani ati awon ọmọ lẹyin rẹ yi o tu ọ sile titi lai.

Jẹ ki Jesu gba isakoso gẹgẹ bi Oluwa lori aye rẹ loni. Iye ayeraye nduro de ọ.

Ti o ba fe ki a gbadura fun o, jọwọ pe ile isẹ iranṣẹ Track Ministry lori +234 818 211 7722 tabi ki o fi iwe ranse si wa lori imeeli yemdoo7@yahoo.com

Ki Oluwa bukun fun ọ.

READ THE TRACT