Mo ma n gbọ ti awọn eniyan ma’n da asa “Ọrun Apaadi, Rara!” Eyi ti awon elede oyinbo npe ni “Hell No!” papa julo ni aarin awọn ara ilẹ Amirika to wọn ba fẹ se afihan bi ọrọ naa se ka wọn lara si.
Ọrun apaadi kiise aṣa rara! Ọrọ orukọ ni, eyi ti o tumọ si agbegbe ati ibugbe ayeraye fun satani ati awọn ọmọ leyin rọ. O jẹ ibi ti eniyan ko ti le kuro o kun fun ipayinkeke, o si tun kun fun inira ayeraye eyi ti a ni oore ofe lati ma je alabapin nibe niisinsinyi. O ko ni fẹ lo igbẹyin aye rẹ nibẹ.
Ayanfe, ọrun apaadi wa! Orun rere wa! Jesu ni ona kan sọsọ si ọrun rere nibiti awọn onigbagbo ninu rẹ ati awọn ọmọ leyin rẹ yio ti lo ayeraye.
Jesu sọ nini iwe Johanu 14:6 pe “Emi ni Ona, Otitọ ati Iye”, ti o ba jọwọ aye re fun Jesu loni, ọrun apaadi ko ni jẹ ibugbe ayeraye rẹ. Otiti Iyinrere Jesu Kristi yi o tọ ọ si igbe aye ainipekun ninu iwa bi Olorun, yi o si dari re si iye ayeraye ni ọrun. Eyi ni ipinnu ti oni lati pinnu loni, ọla le pẹ ju!
Mo n wo aworan ijanba ina ti o lagbara to sele ni ilu Kalifonia U.S.A, eyi ti omokunrin mi ti ọjo ori rẹ n se mẹrindinlogun sọ wipe “ Iya mi, aworan yii dabi aworan orun apaadi ninu ere tiata”.
Ayanfe ọrun apaadi buru jọjọ, o tobi ko si ni opin. Pana pana kan ko le pa a. Idi niyi ti o fi ṣe pataki fun ọ lati ronupiwada loni. Gba Jesu Kristi sinu aye rẹ gẹgẹ bi Oluwa ati Olugbala rẹ ki o le yọ ọ ninu ewu ọrun apaadi. Ti o ba se ipinu yi, inu wa yi o dun lati gbadura pẹlu re.
Fun alaye tabi ibeere, ẹ pe tabi fi iwe ransẹ fun ẹbẹ adura tabi igbaniniyanju
WhatsApp No: +234 818 211 7722, Imeeli: yemdoo7@yahoo.com
Ni afikun, o ni lati darapọ mọ ijọ onigbagbo nibiti wọn o ti maa fi ọrọ Ọlọrun lati inu Bibeli bọ emi rẹ fun idagbasoke ninu ẹmi. Se iwẹ mimọ nipa omi ati ẹmimimọ. O le padanu ohunkohun ninu aye yi, ṣugbon ri daju wipe o ko padanu Ọrun.
Oluwa a bukun fun o l’orukọ Jesu Kristi, Amin!